Discover millions of ebooks, audiobooks, and so much more with a free trial

Only $11.99/month after trial. Cancel anytime.

Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi?
Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi?
Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi?
Ebook408 pages6 hours

Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi?

Rating: 3.5 out of 5 stars

3.5/5

()

Read preview

About this ebook

Àkọ́lé ẹ̀kọ́ yìí gan an ni “lati di àtúnbí níti omi ati ti Ẹ̀mí.” Ó ní ìpìlẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ yìí. Ní èdè mìíràn, ìwé yìí fi nyé wa gedegbe ohun tí àtúnbí jẹ́ ati bí a ti lè di àtúnbí níti omi ati ti Ẹ̀mí ní ìbámu pẹlu Bibeli. Omi túmọ̀sí ìrìbọmi nínú odò Jọrdani Bibeli sì wipe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa pátá ni ó ti rékọjá sórí Jesu nigbati Ó ṣe ìrìbọmi ní ọ̀dọ̀ Johannu Onítẹ̀bọmi. Johannu ni aṣojú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí Ó sì tún jẹ̀ àrọ́mọdọ́mọ Aaroni Olórí alufa. Aaroni gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ewúrẹ́ alààyè náà ó sì kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli ti ọdọdún sórí rẹ̀ ní ọjọ́ ètùtù. Èyí jẹ́ òjìjí ohun rere tí mbọ̀ wá. Ìrìbọmi Jesu ni àpẹẹrẹ ètò ìgbọ́wọ́lé. Jesu ṣe ìrìbọmi ní ìlànà ètò ìgbọ́wọ́lé lórí nínú odò Jọrdani. Nitoridi èyí Ó kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aiyé yìí lọ nípasẹ̀ ìrìbọmi Rẹ̀. Ó sì kú lórí àgbélèbú lati san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni ni kò mọ ìdí tí
Jesu fi ṣe ìrìbọmi ní ọ̀dọ̀ Johannu Onítẹ̀bọmi nínú odò Jọrdani. Ìrìbọmi Jesu ni kókó ọ̀rọ̀ ìwé yìí, ati apákan tí ó jẹ́ dandan sí ìhìnrere ti omi ati ti Ẹ̀mí. A lè di àtúnbí bí a bá nígbàgbọ́ sí ìrìbọmi ti Jesu ati ti ikú Rẹ̀ lórí igi àgbélèbú.

LanguageYoruba
PublisherPaul C. Jong
Release dateOct 9, 2020
ISBN9788965321996
Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi?

Reviews for Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi?

Rating: 3.25 out of 5 stars
3.5/5

4 ratings0 reviews

What did you think?

Tap to rate

Review must be at least 10 words

    Book preview

    Njẹ Nitootọ Iwọ Di Atunbi Ni Ti Omi Ati Ẹmi Bi? - Paul C. Jong

    paul_Pj01india_coverFrontflap_Yoruba01.gif1st_page

    NJẸ NITOOTỌ IWỌ DI ATUNBI NI TI OMI ATI ẸMI BI?

    Smashwords Edition

    Copyright 2023 by Hephzibah Publishing House

    Àtùnjeyẹwo Àtùnṣé A kò fun ẹnikẹni ni aṣẹ lati ṣe ẹdà iwe yi tabi fi ṣe òwò igbapada tabi àtàgbè ni ọnakọnà tabi ya tabi ṣe agbasilẹ rẹ laigba aṣẹ lọwọ onkọwe yi. Awọn ẹsẹ Bibeli tí a lò ni Bibeli Mímọ́ ti Atọ́ka.

    ISBN 978-89-6532-199-6

    Design by Min-soo Kim

    Illustration by Young-ae Kim

    Printed in Korea

    IKÍNÌ ATI ÍDÚPẸ

    A nfi asiko yi n fi ọpẹ pataki fun Oluwa fun ọrọ igbala ati ibukùn ti o fi fun wa pẹlu Ihinrere Omi ati Ẹmi.

    A si tun n fi ọpẹ pataki fun gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun. Pẹlu arakunrin wa Rev. John K. Shin ati arabirin wa Sister Sangmin Lee, ẹniti o pèsè aiye silẹ fun ati tẹ iwe yi jade, si arabirin Mrs Jungpil sul ti o ṣe itumọ rẹ si ede. ati si gbogbo awọn arakunrin ati arabirin Elaine Dawe ti ile-iwe giga (Unisersity) Kangwon ati arabirin Ross Wallace ti Korea times. Won ṣe iṣẹ takuntakun lori iwe yi. A dupẹ lọwọ gbogbo yin patapata lẹẹkan si.

    Mo ni lero ati ninu adura pe iwe yi ati tapes ti a fi pẹlu rẹ yio ran ọpọlọpọ ọkàn lọwọ lati di atùnbi, Mo si fẹ fi ọpọlọpọ ọpẹ fun gbogbo awọn ti wọn ṣiṣẹ takun takun Pẹlu wa.

    Mo si n fẹ ni tootọ pe Oluwa wa yio gba wa laiye lati kede Ihinrere atùnbi ninu Omi ati Ẹmi Jake jado gbogbo agbaiye gbọwọ awọn ti o gbagbọ ninu Jesu. Pẹlu igbagbọ ti kii kù.

    Mo dupẹ lọwọ Oluwa.

    PAUL C. JONG

    0Preface.jpg

    ỌRỌ IṢAAJU

    A NÍ LATI DÍ ATÙNBI NINU OMI ATI ẸMI

    Ọlọrun nigbati ó dá ọrun ati aiye ni ibẹrẹ, o si tun da aiye ainipẹkun, ọrun rere ati ina-apâdi. O si tun da èníyàn ni aworan ara rẹ, ṣugbọn, lati igba ọkunrin akọkọ, ni Adamu ti dẹṣẹ niwaju Ọlọrun lati igba naa ni gbogbo èníyàn ní lati kù lẹẹkan ṣoṣo ati pe Níwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo èníyàn lati kù lẹẹkanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ (Heberu 9:27).

    Ikù wa ninu ara ni ọna si iyé ainipẹkun ẹnikẹni ti ko ba ni ẹṣẹ kankan ni yio wọ ijọba ọrun aiyeraiye ti nwọn yio si ni ayọ aiyeraiye awọn ni yio jẹ Ọmọ Ọlọrun. Awọn ẹlẹṣẹ ni a o ko da sinu Adugun ina ajooku. Bi a ti kọ ninu iwe (Ifihan ori 20:10) ti nwọn yio si maa jiya ni ọsan ati òrun tití aiyeraye.

    Nitorina, ni oṣe jẹ dandan fun gbogbo eniyan lati di atùnbi. A ni lati di atùnbi ninu igbagbọ wa, ani lati ni irapada kuro ninu gbogbo ẹṣẹ wa ki a si di olododo niwaju Ọlọrun. Nigbanaa ni a o ni anfani lati wọ inu ijọba ọrun aiyeraye. Bibeli wipe, Bikoṣepe a fi Omi ati Ẹmi bi èníyàn on ko le wọ ijọba Ọlọrun. (Johannu ori 3:5). Lati ti di atùnbi ninu Omi ati Ẹmi ni ọna kan ṣoṣo ti a le gba wọnu ijọba Ọlọrun.

    Irù ki wa ni Omi ati Ẹmi yi ti o fun wa ni anfani lati di atùnbi? Omi ninu Bibeli tumọnsi Iribọmi Jesu.

    Kini idi ti Jesu ti o jẹ Ọlọrun fi ṣe Iribọmi lọdọ Johannu Baptisi? Njẹ o ṣe eyi lati fi rẹ ara rẹ silẹ bi? Njẹ o ṣe eyi lati kede ara rẹ pe oun ni Messayah naa bi? Rara o.

    Nigbati Jesu ṣe Iribọmi gbọwọ Johannu Baptisi nipasẹ igbọwọlé Ki Aaroni ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ mejeji lé ori ewurẹ alaaye na, ki o si jẹwọ gbogbo aiṣedede awọn ọmọ Israeli sori rẹ̀, ati gbogbo irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn; ki o si fi wọn lé ori ewurẹ na, ki o si ti ọwọ́ ẹniti o yẹ rán a lọ si ijù (Lefitiku 16:21) ‘nipa iwa ododo ẹnikan’ (Jesu) ẹbun ọfẹ de sori gbogbo eniyan. Fun idalare si iye (Romu 5:18) eyi yi ni o mú gbogbo ẹṣẹ araiye lọ.

    Ninu Iwe Majẹmu lailai, Ọlọrun fun Israeli ni ófin aanu rẹ si irapada. Bi o ti ri ni eyi ní ọjọ étutu, gbogbo ẹṣẹ Israeli ni a o mú kuro gbọwọ olori alufa, Aaroni nipa gbigbé ọwọ sori ewurẹ alaayè naa yio si ko gbogbo ẹṣẹ wọn sori ewurẹ alaayé naa.

    Eyiyi ni ọrọ asọtẹlẹ, ti a ti sọ tẹlẹ nipa irúbọ étùtù aiyeraiye. Eyi si ni a fi han ni tootọ pe gbogbo ẹṣẹ araiye pata ni a ó kó lẹẹkanṣoṣo sori Jesu ẹniti o wá ninu ẹya ara èníyàn gẹgẹbi ifẹ ti Baba. O si ṣe Iribọmi lati ọwọ Johannu Onitẹbọmi ẹniti o jẹ arọmọdọmọ Aaroni ti o si jẹ aṣoju gbogbo èníyàn.

    Nigbati jesu ṣe Iribọmi tan o wi fun Johannu pe jọwọ rẹ bẹẹ na:nitori bẹẹ ni o yẹ fun wa lati mú gbogbo ododo ṣẹ. (Matteu 3:15).

    Ni ibiyi, eyi tumonsi pe nipa èto igbọwọ le ni li ori ní ọna ti Johannu gba ko gbogbo ẹṣẹ agbaiye pata sori Jesu Kristi, ni wipe ki gbogbo ododo le ṣẹ fun gbogbo wa. Apele ọrọ ododo jẹ dikaiosune ni ede Giriki ti o tumọn si pe ki èníyàn ṣe ododo ni ìwa tabi ni íṣé, pẹlu iṣẹ ododo ti o yẹ.

    Jesu mú gbogbo ododo ṣẹ ti o si sọ gbogbo èníyàn di olododo nipa Iribọmi rẹ gba ọwọ Johannu Onitẹbọmi nitoripe Jesu ti ko gbogbo ẹṣẹ araiye lọ nipa Iribọmi rẹ, nigbana ni Johannu ṣe ẹri rẹ ni ọjọ keji ti o si wipe, woo ọdọ agutan Ọlọrun ẹniti o ko ẹṣẹ aiye lọ. (Ihinrere Johannu 1:29).

    Jesu lọ lori Igi agbelebu nigbati o gba gbogbo ẹṣẹ aiye yi mọra, o si gba idajọ fun gbogbo ẹṣẹ ati aiṣedede wa nigbati o ṣe Iribọmi. O si kù lori Igi agbelebu ti o wipe: O pari (Ihinrere Johannu 19:30). O ko gbogbo ẹṣẹ wa sori ara rẹ ti o si gba idajọ ikẹhin dipo wa.

    IRIBỌMI JESU NI APẸRẸ IGBALÀ WA

    Nitorina ti a ko bani igbagbọ ninu Iribomi Jesu a ko le ni igbala. Nitori idi eyi ni Aposteli Peteru fi wipe Iribomi ti Omi rẹ ni o gbawa là (1 Peteru 3:21).

    Loni, ọpọlọpọ èníyàn ni nwon gba Jesu gbọ ti ko ni igbagbọ fun Iribomi rẹ ti o ṣe ninu odo Jordani eyi yi ni "Omi" ti won si ni igbagbọ fun ikù rẹ nikan lori Igi agbelebu. Njẹ iru igbagbọ yi le gba awa ẹlẹṣẹ la bi? Njẹ awa leri irapada kuro ninu ẹṣẹ wa nigbati awa ba nigbagbọ ninu Ẹjẹ Jesu nikan bi?

    Rara, a ko le ni irapada niwaju Ọlọrun pelu igbagbọ ti o da lori Ikù Jesu kristi lori Igi agbélebu nikan.

    Ninu iwe Majemu lailai nigbati awọn ọmọ israeli maa n mu ẹbọ wa fun ètutu, ko le e dọgba ti wọn ba pa éwurẹ alaaye naa nigbati wọn ko ba kọkọ gbe ọwọ le e lori, lati pe gbogbo ẹmi ẹṣẹ ati aiṣedede wọn sori éwure alaaye na. Nitorina igbagbo wa yio je igbagbọ asan ati igbagbọ ti ko pe nigbati a ba n gba agbélebu Jesu Kristi nikan gbọ laini gbagbọ si Iribomi rẹ.

    Nitori eyi ni aposteli Peteru ti sọ pe: Eyi ni Iribomi ti o gbawalà nisinsinyi nipa Ajinde Jesu Kristi (1 Peteru 3:21)

    Gẹgẹbi ọpọlọpọ eniyan ti ko gbagbọ fun ikun omi niigba aiye Noah ti ṣegbe, bẹẹ gẹgẹ ni awọn ti wọn ko bani gbagbọ si Omi ani Iribomi ti Jesu Kristi paapa yio ṣegbe laisi aniani.

    Igbagbọ pipe ti o funni ni igbalà tooto ni igbagbọ ninu "Jesu Kristi, eniti o wa nipa Omi ati Ẹjẹ" (1 Johannnu 5:6) Ani lati gbagbọ dandan ninu Iribomi ati Iku Jesu Kriti loriIigi Agbelebu.

    Aposteli Johannu wipe igbagbọ tootọ, ti o si pe nipe ki a gbagbọ ninu ẹri ti Ẹmi, ti Omi ati ti Ẹjẹ (1 Johannu 5:8).

    Nitorina igbagbọ pipe ni n muni gbagbo bayi pe Jesu ni Ọlọrun fun rarẹ ẹniti o wa ninu ẹya ara èníyàn nipase Ẹmi Mimọ ti a bi nipase Maria Wundia, ti o si ko gbogbo ẹṣẹ araiye lọ, nigbati oṣe Iribọmi ninu odo Jordani lati ọwọ́ Johannu Onitẹbọmi, eniti oṣe oniduro fun gbogbo ẹda alaaye. Nitorina Jesu ko gbogbo ẹṣẹ araiye lọ nigbati o lọ sori Igi agbelebu, ni bi ti o ti gba idajọ Ikù fun gbogbo wa. Nitorina ni Ihinrere yi ko le jẹ pipe nigbati a ko ba kede Iribomi rẹ eyi yi ni Omi; pẹlupẹlu bi a ba ti le gba Jesu gbọ lai si ti Iribomi rẹ ninu a ki yio ni igbala aiyeraiye.

    IPILẸ ITÀN ẸRI TI IHINRERE TOOTỌ FI SỌNU SI IJỌ TABI SI ONIGBAGBỌ

    Kini idi ti o fi jẹ wipe ni ode oni, Ihinrere-tootọ ti Omi ati ti Ẹmi fi ṣe ọwọn to bẹẹ, ti Ihinrere odi fi tan ka gbogbo agbaiye to bẹẹ?

    Nigbati Jesu jinde ti o si lọ si oke ọrun, ni awon Aposteli ti ma n kede Ihinrere Omi ati Ẹjẹ yi. Ti a ba ka iwe Majemu Titun daradara a o ri wipe awọn ti wọn kọ iwe Bibeli yi awọn bii Aposteli Paulu, Peteru ati Johannu. Ṣugbon gbogbo awọn Aposteli ati awọn ojiṣẹ ti ijọ igbanì nwọn ti kede Ihunrere Omi ati Ẹmi yi daradara.

    Nitorina ni eṣu ti n gbero lati ibẹrẹ ati fi opìn si Ihinrere yi ati lati yọ agbara iye kuro ninu ijọ. Nigbana, lati gba Edict Milan 313 A.D. (lẹhin Ikù Oluwa wa Jesu Kristi) ni ijọ kristiẹni ti ṣubu sinu u pakute Satani, eyi yi ni eṣu. Àwọn agbára ìṣèlú ti Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ní pàṣípààrọ̀ fún dídá ẹ̀sìn Kristẹni mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn ìjọba, ní agbára láti ní ìdúróṣinṣin nínú ìṣèlú.

    Ni abẹ agbara ijọba ti awọn ara Romu (Roman Empire) ni nwọn ti sọ kristiẹni di Ẹsin Ijọba labẹ wipe ki wọn baa leni agbara ijọba pẹlu eroungba wipe ẹnikẹni tio ba wa sinu ijọ yio ṣe iribọmi, Ijọba Romu ṣe amojuto iṣọkan lori awọn ẹgbẹ colonies.

    Nitori eyí gan ni o fa iwa ati Iṣe Awọn Aposteli ti n ṣe a tun awọn ọrọ wọn. Nitorina ni Ihinrere tootọ fi dọgba pẹlu Bibeli, eyi yi ni wipe "Bi Ihinrere Omi ati Ẹmi ti o fun wa ni agbara, Ẹmi Mimọ ati ọpọlọpọ igbẹkẹle." (Tessalonika 1:5) ti o sọnu patapata. Gẹgẹbi Satani ti ṣeto rẹ, Ihinrere wa di Ihinrere irọ ti ko sọ eniyan di atunbi ti gbérù ti nwọn si pọ lọ rẹpẹtẹ ni gbogbo aiye.

    Lẹhin ẹgbẹrun ọdun ni igba Edict Milan ni awọn ẹgbẹ ọkunrin ti kristiẹni ti fi iṣẹ wọn ru ọpọlọpọ loju ni igba na ati wipeni asiko naa ni oniruuru awọn iwa atunṣe fun ilọsiwaju ni wọn gbe kalẹ kaakiri gbogbo ilẹ alawọ funfun ni igba naa, ti wọn si n rọ awọn èníyàn pada si di ọrọ Ọlọrun, ore-ọfẹ Ọlọrun ati igbagbọ fun Ọlọrun, ti ko si si ẹnikan ṣoṣo ninu wọn ti tio ti ba Ihinrere tootọ pade, Ihinrere Omi ati Ẹjẹ.

    Ihinrere tootọ yi ni a fi pamọ laaye ni ọwọ awọn diẹ ti wọn tẹle ọrọ Ihinrere yi lati igba aiye awọn Aposteli. Gẹgẹbi orisun omi ti o fi ara pamọ sinu ilẹ, ti o tun jade lẹẹkan si ni gbangba ti o farahan lẹkan si ni awọn ọjọ ikẹhin yi pe ki a le kede rẹ jakejado gbogbo agbaiye.

    ÉYÍ YÌ NI ÍWÉ AKỌKỌ TI N KEDE IHINRERE TI IRIBỌMI TI JESU GẸGẸBI ATI KỌ Ọ NINU BIBELI MIMỌ

    Eyí yí ni iwe akọkọ ti asiko yi lati kede Ihinrere Iribọmi ati Ẹjẹ Jesu gẹgẹbi iwe-mimọ ti kọ ọ. Ihinrere tootọ nsọ fun wa gbangba wipe Jesu Kristi wa ko gbogbo ẹṣẹ wa ninu Iribọmi rẹ, ti o si gba idajọ Ikù lori Igi Agbelebu nitori ẹṣẹ wa ti o o ninu odo Jordani. O dami loju gbangba wipe ko si iwe miran ti o kede Ihinrere Omi.

    Nibiti ẹrọ igbalode ti wa ti ọpọlọpọ ti n ṣe iwadi imọ gbogbo lori ẹrọ (internet) mo gbiyanju lati ṣe alabapade awọn ajihinrere ti nwọn kede ohun ti o fi ara pamọ ninu Iribọmi Jesu pẹlu igbagbọ. Ṣugbọn, emi ko ni anfani rẹ ni igbana ni mo wa pinnu lati tẹ iwe yi ni ede Yorouba.

    Ni igbati ikun omi de ti o bo gbogbo aiye mọlẹ bẹẹ ni ko si ẹnikan ti yio ye lati mu omi. Bẹẹ na ni ọpọlọpọ èníyàn mbẹ ti nwọn si npe ara wọn ni iranṣẹ Ọlọrun ti wọn i nkede Ihinrere odi ti ko si si ọkan ṣoṣo ninu wọn ti o le funni ni iye tootọ.

    Obinrin ara Samaria ti ma nfi ojoojumọ mu omi kanga Jacọbu ko lee pa oungbẹ ẹmi ara rẹ, ṣugbọn nigbati o mu Omi ye ti Jesu Kristi, ori igbalà ati ni ẹsẹkẹsẹ ni o pa oungbẹ rẹ titi aiyeraiye.

    O ni iyè ti Jesu ti nṣan ninu iwe yi ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi yi yio ye, yio si ri igbalà kuro ninu ẹṣẹ rẹ titi aiyeraiye. Ẹni na ki yio si ninu igbékùn ẹṣẹ mọ. Bẹẹ si ni ẹṣẹ ko si tun ni ipa lori rẹ mọ. Omi iye yi yio si maa ṣan ninu ẹni naa si ẹlomiran ti yio si maa pa oungbẹ ọkàn ẹlomiran ni agbegbe rẹ tabi ni ayika rẹ.

    Ẹ JẸ KI A JẸ OṢIṢẸ ỌLỌRUN, ALATUNṢE IBAJẸ

    Asiko igba ikẹhin ni a wa yi. O jẹ asiko ti ẹṣẹ gbogbo araiye ti pọ lapọju, idajọ ododo Ọlọrun si ti sunmọ tosi. Awọn ọjọgbọn aiye yi man gbiyanju ati ṣe ẹda awọn nkan alaaye bi agutan bi éré ati bẹẹbẹ lọ, bẹẹni ọpọlọpọ èníyàn si ṣetan ati gba iru eyi gbọ.

    Loni yi, ati nkọ ile-iṣọ-agbara miran. Ni igba kan ri ti eniyan ngbiyanju lati ṣe iru nkan bẹẹ ni Ọlọrun si da ede wọn ru. Ni igba yi si ni igba ijiya nla ti Ọlọrun yio da ibinu rẹ sori ilẹ-aiye ati idajọ aiyeraiye ti yio de awọn ọkàn ti o ṣegbe ti wọn ko ti i di atunbi.

    Nitorina, mo nrọ yi, mo si tun nbẹ yin wipe ki ẹ fi ẹsọ fi tẹle iwe yi daradara. Mo n gbadura wipe ki ẹ di atunbi Omi ati Ẹmi. Iwe yi ni nkede Ihinrere gẹgẹbi atikọọ ninu Iwé-Mimọ.

    A ti kọ ọ pe: Bi ẹyin ba duro ninu ọrọ mi, nigbana ni ẹyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitootọ. Ẹ o si mọ otitọ, otitọ yio si sọ yin di ominira. (Johannu 8:31-32). Ani lati mọ otitọ nipasẹ iwe yi ki a si ni itusilẹ kuro lọwọ ẹṣẹ ati ik! A ni lati jẹ ẹni irapada ki a ba le jogun iye-ainipẹkùn ninu rẹ!

    Ẹjẹ ki a jọ ṣe iṣẹ Baba ni apapọ lati gba awọn ọkàn ti o ti ṣako lọ nipa kikede Ihinrere Omi ati Ẹmi. Mo ní léro wipe Ihinrere tootọ yi, yio tan jakejado gbogbo agbaiye lẹẹkan si. Mo si ni idaniloju wipe Ihinrere tootọ yi ni yio mu ṣe atunsilẹ gbogbo awọn iwa ibajẹ ti igbagbọ Kristiẹni ti ode oni yi pẹlu ọrọ ododo rẹ.

    Awọn tirẹ yio mọ ibi ahoro atijọ wọnni, iwọ o gbe ipilẹ iran ọpọlọpọ ro, a o si ma pe ọ ni alatunṣe ẹya ni, olumupada ọna wọnni lati gbe inu rẹ. (Isaiah 58:12).

    Dajudaju ọpọlọpọ ninu yin ni ko ti ṣe alabapade Ihinrere ti atunbi ninu Omi ati Ẹmi. Nitorina ni mo ṣe gbiyanju lati le tẹnumọ Ihinrere ti Iribọmi ti Jesu Kristi ati Ikù rẹ lori Igi Agbelebu ninu awọn iwaasu mi.

    Ti ko ba si Iribọmi jesu, Ikù rẹ lori Igi Agbelebu ko ni ni itumọn kan fun gbogbo wa. Idi niyi ti mo fi ntẹnumọn pẹlu agbara ati idaniloju iṣẹ mi.

    Ati èro mi ni lati fi ọrọ otitọ yi yẹ ẹnikẹniti o ba n ka iwe yi titi di igba ti ẹyin yio jere ibukun ti mbẹ ninu Ihinrere Omi (eyi yi ni Iribọmi Jesu) ati Ẹmi, emi yio tunbọ maa tẹnumọn ọn si fun yi.

    Mo si nfẹ pe ki gbogbo yin pata ni igbagbọ ninu Ihinrere ti Iribọmi ati ẹjẹ rẹ ki a ba le ni igbala kuro ninu ẹṣẹ wa. Mo si ni idaniloju wipe iwe yi yio tọ yin sọna lati di atunbi ninu Omi ati Ẹmi.

    Awọn akoonu

    ỌRỌ IṢAAJU

    APA KINNI: IWAASU

    1. Ani lati kọkọ mọ nipa ẹṣẹ wa ati lati ni irapada (Marku 7:8-9, 20-23)

    2. A bi èníyàn ni ẹlẹṣẹ (Marku 7:20-23)

    3. Ti a ba n ṣe iṣẹ nipa òfin njẹ ole gbawa la bi? (Luku 10:25-30)

    4. Irapada ayeraye (Johannu 8:1-12)

    5 Iribọmi Jesu ati Etutu fun ẹṣẹ (Matteu 3:13-17)

    6. Jesu Kristi o Wá nipa Omi, Ẹjẹ ati Ẹmi (1 Johannu 5:1-12)

    7. Iribọmi jesu ni apẹẹrẹ igbala fun gbogbo ẹlẹṣẹ (1 Peteru 3:20-22)

    8. Ihinrere ti ọpọlọpọ Etutu (Johannu 13:1-17)

    APA KEJI: ÀFIKÚN

    1. Ijẹri Igbalà

    2. Àfikún ati alayé

    3. Ibeere ati Idahun

    Sermon01.gif01.jpg

    Ani lati kọkọ mọ nipa ẹṣẹ wa ati lati ni irapada

    < Marku 7:8-9 >

    Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́.

    < Marku 7:20-23 >

    O si wipe, ‘Eyi ti o ti inu enia jade, eyini ni isọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania, Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère: Lati inu wá ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ́.’

    Ni akọkọ na, mo fẹ lati sọ ohun ti ẹṣẹ jẹ tabi itumọn ẹṣẹ. Ẹṣẹ ni itumọn miran si Ọlọrun bakan na ni ẹṣẹ si tun ni itumọn miran si èníyàn. Apele ẹṣẹ ni ede Giriki ni ‘αμαρτία (hamartia)’ ti o tumọnsi ṣi ami naa, ni ede miran ni ki eniyan ṣe aṣiṣe. Ẹṣẹ ni wipe ki a kọ eti kunkun si òfin Ọlọrun. Ẹ jẹ ki a wo itumọn ti eniyan ni si ẹṣẹ.

    A nwo ẹṣẹ nipa awọn èro ọkàn wa, ni ọna miran gẹgẹbi aigbọran si òfin Ọlọrun si idajọ aṣiṣé tabi aiṣedede lati inu ọkàn wa ti eyi si jẹ bi ẹri ọkàn fun kaluku wa.

    Eyiyi si jẹ idajọ ẹnikọọkan wa ati wipe iru iṣe bẹ, a le kaa si ẹṣẹ tabi a yi tẹlẹ iṣe idajọ ẹni kọọkan wa. Nitori eyi ni Ọlọrun fi fun wa ni awọn oniruru ófin 613 fun lilo lati le mọ ẹṣẹ.

    Aworan ti mbẹ ni isalẹ yi ni apẹrẹ ẹṣẹ èníyàn.

    no1_20p

    A ko gbọdọ fi ẹṣẹ wa wé èro ọkàn tabi iwà wá laarin ẹgbẹ.

    Ẹṣẹ inu èro-ọkàn wa ki i ṣe gẹgẹbi Ọlọrun ti pee, nitorina, a ko gbọdọ fi éti si èrò ọkàn wa ṣugbọn, ki a kuku fi ipilẹ èro wa sori ohun ti Ọlọrun pe ni ẹṣẹ.

    Ẹni kọkan ni o mọn ohun ti ẹṣẹ jẹ. Awọn kan nwo ẹṣẹ bi aṣiṣe wọn, ẹlomiran nwó bi iwa búburú.

    Fun apẹẹrẹ ni ilu Korea, awọn èníyàn ma nṣe itọju sááre okù (iboji okù) awọn obi wọn, ti wọn yio bo iboji na pẹlu koriko titi di igba ti wọn yio fi kù. Ṣugbọn ninu awọn ẹya awọn iran mi, ti Guinea titun, ni tiwọn, wọn maa nfi ọwọ fun okù awọn obi wọn ti wọn ti kù nipa pín-pín ẹran ara okù yi laarin awọn ẹbi. (Boya gan ni wọn tilẹ maa nse ẹran naa ki wọn to jẹẹ). Mo ni lèro wipe wọn ma nṣe eyi lati fi daabo bo ẹran-okù yi, nitori idin. Aṣa yi fi nye wa wipe èro ẹṣẹ gbọdọ yatọ, iwa rere laarin ẹgbẹ, ni ibomiran.

    O le jẹ iwa ara oko, ẹṣẹ ati iwa rere le fi ara pẹ rawọn amọ Bibeli, ẹṣẹ ni kọ eti-ikun tabi ṣe aigbọran si ófin Ọlọrun. Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe. O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin kọ̀ ofin Ọlọrun silẹ, ki ẹnyin ki o le pa ofin atọwọdọwọ ti nyin mọ́. (Marku 7:8-9). Ọlọrun ko wo iṣe wa ninu ara, ọkàn wa ni Ọlọrun nwo.

    IṢE ATI IWA ENIYAN ẸṢẸ NI NIWAJU ỌLỌRUN

    Mo fẹ ki nsọ fun yin ohun ti nṣe ẹṣẹ niwaju Ọlọrun. Oun ni lati má gbe igbesẹ gẹgẹbi ifẹ Ọlọrun, oun kan naa ni lati má gba ọrọ rẹ gbọ. Ọlọrun wipe ẹṣẹ ni lati gbe igbe aiye awọn Farisi, ti wọn kọ òfin Ọlọrun silẹ ti wọn si mu ẹkọ ibilẹ wọn ni pataki. Jesu mọ èro wọn o si pe wọn ni eke ẹyin ara Farisi.

    Ọlọrun wo ni ẹyin gbagbọ bi? Njẹ ẹyin nfi ọwọ ati ògo fun mi bi? Ẹyin si ṣogo nipa orukọ mi, ṣugbọn, njẹ ẹyin nfi ọwọ fun mi bi? Ọpọ èníyàn nwo oju ti wọn si nfi oju tẹmbẹlu ọrọ rẹ. Ẹṣẹ ti o bùru ju ni ki a fi oju tẹmbẹlu wo ọrọ rẹ. Njẹ ẹyin mọ eyi bi?

    Awọn alailera wa ni aṣiṣe wa, ni ṣoki, oun ni aiṣedede wa, awọn aṣiṣe ti a nṣe ati iwa aitọ wa ti a nhu ni iwa nipa aipe ninu ara wa kọ ni ẹṣẹ, ṣugbon ti wọn jẹ aṣiṣe. Ọlọrun fi iyatọ sinu ẹṣẹati aiṣedede. Awọn ti wọn kọ ọrọ Ọlọrun ni ẹlẹṣẹ bi wọn ko ba tilẹ ni aṣiṣe kakan ẹlẹṣẹ paraku ni wọn niwaju Ọlọrun. Nitorina ni Jesu ba awọn ara Farisi wi.

    Ninu iwe Majẹmu lailai lati Genesisi de Deutoronomi, awọn òfin kan wa ti wọn nsọ ohun ti o yẹ ki a ṣe ati ohun ti ko yẹ ki a ṣe. Awọn wọnyi ni ọrọ Ọlọrun, ófin rẹ. A ko lee ṣe ófin yi ni pipé ni 100%, o ṣeeṣe ki eniyan ma ri nipa ófin, ṣugbọn ani lati mọ wọn gẹgẹbi ófin Ọlọrun. o fi wọn fun wa lati ibẹrẹ a si ni lati gba wọn gẹgẹbi ọrọ Ọlọrun.

    Ni àtétékọṣe Ọlọrun dá ọrun on aiye (Johannu 1:1). O si wipe, Ki imọlẹ ki o wà: imọlẹ si wà (Genesisi 1:3) O si da ohun gbogbo. Lo si wa fi ofin rẹ lelẹ.

    Ni àtètèkọṣe ni ọrọ ti wa, ọrọ si wa pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun ̟ si ni ọrọ naa. Ọrọ na si di ara, o si mba wa gbe oun si ni ọrọ na (Johannu 1:1, 14). Bawo ni Ọlọru n ṣe fi ara rẹ han wa? o fi ara rẹ han wa nípa òfin rẹ nitoripé Ọlọrun ni ọrọ Ẹmi. Nitorinaa kinni a npe Bibeli? A npe ni ọrọ Ọlọrun.

    O si nsọ fun wa nibi pe; "Nitoriti ẹyin kọ òfin Ọlọrun silẹ ti ẹyin si gba aṣa ibilẹ ti èníyàn." Ẹgbẹta ole-mẹtala (613) ni mbẹ ninu òfin Ọlọrun ṣe eyi, ma si ṣe eyi, bọwọ fun iya on baba rẹ...... ati bẹẹbẹẹ lọ. Ninu iwe Lefitiku, o sọ nipa bi ọkunrin ati obinrin ti maa nṣe ati ohun ti wọn le ṣe nigbati ẹranko-ile ba ko sinu ọgbun tabi sinu koto.

    Oniruru òfin ni mbẹ ninu òfin Ọlọrun. Eyi ti gbogbo rẹ ni apapọ jẹ ẹtala le lẹgbẹta (613 articles). Nigbati wọn ki i ṣe ọrọ èníyàn ani lati ni ironu atun ro dáradára nipa rẹ. Botilẹjẹpe o ko ni ipá agbti agbárá lati le ṣe òfin rẹ, sibẹsibẹ ani lati le jọwọ ara wa fun ati pe ki a si gbaagbọ.

    Njẹ a ri ẹṣẹ kan ninu ọrọ Ọlọrun ti ko tọ, ti ko yẹ tabi ti ko dara? awọn ara Farisi wọn kọ òfin Ọlọrun ti wọn si di aṣa iṣẹnbaye mu ju òfin Ọlọrun. Ọrọ aṣiwaju wọn ṣe pataki fun wọn ju ọrọ Ọlọrun lọ.Nigbati Jesu ṣi mbẹ laiye eyi yi ni ohùn ti o ṣelẹri ati wipe ohùn ti o duun ju ni wipe wọ ko ka ọrọ Ọlọrun si.

    Ọlọrun fun wa ni òfin mẹtala le lẹgbẹta (613) wipe ki a le mọ ẹṣẹ wa ati lati fi han wa pe oun ni otitọ ati Ọlọrun wa mimọ. Nigbati gbogbo wa ti jẹ ẹlẹṣẹ niwaju rẹ ani lati gbe igbe onigbagbọ ati lati gba Jesu ẹniti a ran si wa lati ọdọ Ọlọrun wa nitori ifẹ rẹ fun wa, ani lati gbe igbesi aiyé onigbagbọ.

    Ẹnikẹni ti o pa ọrọ rẹ ti, ti wọn ko si gbaagbọ ni ẹlẹṣẹ. Awọn ti wọn ko lee tẹle ọrọ rẹ naa gaan paapaa ẹlẹṣẹ ni wọn, ṣugbọn ki a kọ ọrọ rẹ silẹ ni ẹṣẹ ti o bùruù ju, awọn ti nwọ nda ẹṣẹ ti o rórò bayi ni wọn yio wọ inu ina apaadi. Ni aígba ọrọ Ọlọrun gbọ ni ẹṣẹ ti o bùrù julọ niwaju rẹ.

    IDI TI ỌLỌRUN FI FUN WA NI ÓFIN

    Kini idi ti Ọlọrun fi fun wa ni òfin? Oun ni lati mọ ẹṣẹ wa ki a si pada si ọdọ rẹ. Ofun wa ni awọn nkan òfin bi ẹgbẹta ole mẹtala (613 articles) wipe ki a ba le mọ ẹṣẹ wa ki a si ni igbalà nipasẹ Jesu Kristi. Idi ni yi ti Ọlọrun fi fun wa ni òfin.

    Iwe Romu ori 3:20 wipe: Nipa iṣẹ òfin ni imọ ẹṣẹ ti wa. Nitorina, a mọ wipe idi ti Ọlọrun fi fun wa ni ófin ki i ṣe pe ki o fi tipátipá mu wa gbe abẹ ófin kọ.

    Njẹ kini ere ti ari gba ninu imọ ti o wá lati ọwọ òfin? Oun ni wipe ati rẹwẹsi julọ lati ṣe igbọràn si òfin lodindin gẹgẹbi o ṣe wà ati wipe a jẹ ẹlẹṣẹ paraku niwaju Ọlọrun. Kini ohun ti o mọ nipa awọn nkan òfin rẹ (613). A mọ nipa awọn aṣiṣe wa ati aini ipá lati yè nipa òfin rẹ. A mọ daju wipe awa ẹda ti Ọlọrun da, a jẹ alailagbara tabi akura èníyàn, bẹẹ gẹgẹ ni atun jẹ ẹlẹṣẹ paraku niwaju rẹ, gbogbo wa ni ani lati wọ inu ina apaadi gẹgẹbi òfin rẹ.

    Nigbati asi ti mọ nipa ẹṣẹ ati ainipa wa lati yè nipa òfin, nigbana nko njẹ kinni ohùn ti o yẹ ki aṣe? Ṣe a o gbiyanju lati di èníyàn pípé ni bi? Rara. A ni lati gbakamu ni wipe ẹlẹṣẹ niwa, gba Jesu gbọ ki o si ri wipe ori irapada ninu iṣẹ igbalà rẹ, ninu Omi ati Ẹmi nigbanaa ni ẹyin yio mọ idi ti o fi yẹ ki a dupẹ fun.

    Idi ti Ọlọrun fi fun wa ni ófin ni pe ki a mọ ẹṣẹ wa ki a si mọ ijiya ti o ọ si awọn ẹṣẹ wọnyi.Lati isinsinyi lọ, ani lati mọ íṣóro ati ni igbala kuro ninu ina apadi laisi Jesu. ti a ba gba Jesu Kristi gbọ gẹgẹbi Olugbalà wa, ni a ti ni irapada ọkàn wa. O fun wa ni òfin lati muwa de ọdọ Olugbalà wa Jesu Kristi.

    Ọlọrun da òfin fun wa lati jẹ ki a mọ bi atijẹ ikida ẹlẹṣẹ si, ati wipe ki o ba le gba ọkàn wa là kuro ninu ẹṣẹ yi. O fun wa ni òfin o si tun ran Ọmọ rẹ kanṣoṣo si wa, Jesu, lati gba gbogbo wa là, nigbati o ko gbogbo ẹṣẹ wa ninu Iribọmi rẹ. Nigbati a ba gba eyi gbọ nigbana ni a ni anfani lati ni igbalà.

    Awa jẹ ẹlẹṣẹ ti ko ni ireti igbalà kankan, ti o si ṣe dandan fun wa wipe ki a gba Jesu gbọ ki a ba lee ni itusilẹ kuro ninu ẹṣẹ wa, ki a ba le jẹ ọmọ rẹ ati wipe ki gbogbo ogo ba le jẹ tirẹ.

    Ani lati jẹ ki o yé yi, ki o yé wà, bẹẹ ni a si ni lati ronu jinlẹ nipa rẹ ati wipe ki a ṣe idajọ fun rawa nipa ọrọ rẹ, nitoripe ohun gbogbo ni o ti ọdọ rẹ wá. A si tun ni lati moyé írapada tootọ ti mbẹ ninu ọrọ rẹ. Eyi yi ni ohun ti o tọ ati igbagbọ tootọ.

    KINI OHUN TI MBẸ NINU ỌKAN ENIYÀN?

    Igbagbọ ni lati bẹrẹ pẹlu ọrọ Ọlọrun a si ni lati gbaagbọ nipa ọrọ rẹ. Bi bẹẹkọ, awa yio ṣubu sinu aṣiṣe. Eyi yio si jẹ aṣiṣe ati igbagbọ ti ko ni otitọ ninu, tabi igbagbọ búburú.

    Nigbati awọn ọmọ ẹhin Jesu ti wọn n jẹun pẹlu ọwọ-ídọtì, wọn ki ba ma ti bawọn wi ti o ba ṣe wipe wọn ti mọ eroungba ọrọ Ọlọrun ni. Ohun ti ọrọ na nsọ fun wa ni wipe ohun kóhun ti o ba wọ inu èníyàn lati ita tabi ode kọ ni n sọ èníyàn di alaimọ, nitori wipe ohun naa yio gba inu ikun ninu ifun titi yio fi jade kuro ninu ara ti ko si ni pa ọkan lara.

    Gẹgẹbi ati kọọ ninu iwe Marku ori 7:20-23 o si wipe: Eyi ti o ti inu èníyàn jade, eyini ni isọ eniyan di alaimọ. Nitori lati inu, lati inu ọkan eniyan ni író búburú ti ijadé wa:Panṣágà, Àgbèrè, Ípàniyàn, Olè, Ojúkòkòrò, Ìwà búburú, Ítanjẹ, Wọbíà, Ojú búburú, Ísọrọ-ódi, Ìgbéraga, Ìwèrè, lati inu wa ni gbogbo nkan wọnyi ti ijade wa, nwọn a si sọ èníyàn di alaimọ. Jesu si wipe èníyàn jẹ ẹlẹṣẹ nitori ti a bi wọn pẹlu ẹṣẹ.

    Njẹ itumọ eyi yé yin bi? a bí wa gẹgẹbi ẹlẹṣẹ nitori pe gbogbo wa jẹ ọmọ Adamu. Ṣugbọn a ko lee ri otitọ nitori ti a ko gbaa bẹẹni a ko si gba gbogbo ohun ti mbẹ ninu ọrọ rẹ gbọ. Nitorina kini ohun ti mbẹ ninu ọkàn èníyàn?

    Iwe Marku yi fi nye wa wipe: Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania, Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère: (Marku 7:21-22).

    A kọ ọ ninu iwe orin Dafidi pe: Nigbati mo ró ọrun rẹ, iṣẹ-íkà rẹ,oṣupá ati irawọ ti iwọ ti ṣe ilana si lẹ kini èníyàn ti iwọ fi nṣe iranti rẹ? (Orin Dafidi 8:3-4).

    Kini idi ti Ọlọrun fi bẹ wá wó? O bẹ wá wó nitoriti o fẹ wa, o dá wa ti o si tun ṣaanu fun awa otoṣi ẹlẹṣẹ. O nu gbogbo ẹṣẹ wa nu kuro o si sọ wa di èníyàn rẹ. Oluwa, Oluwa wa orukọ rẹ ti ni yin to ni gbogbo aiye, ati ni ọrun! (Orin Dafidi 8:1). Ọba Dafidi ma nkọ orin yi ninu iwe Majẹmu lailai nigbati o ri wipe Ọlọrun ni yio jẹ Olugbala ẹlẹṣẹ.

    Ninu iwe Majẹmu titun Aposteli Paulu tun orin yi kọ. O jẹ ohùn iyanu wipe awa ẹda Ọlọrun a le wa jẹ ọmọ rẹ. O ṣe eyi nitori aanu rẹ fun wa. Eyi yi ni ìfẹ Ọlọrun fun wa.

    Ani lati mọ wipe nipa igbiyanju lati ṣe òfin Ọlọrun, afi bi ẹni wipe a npe Ọlọrun ni ija tabi a nfi ndan Ọlọrun wo (challeng). O ṣi tun jẹ iṣẹ igberaga ti o wá lati inu aimọ wa ko si jẹ ohun ti o dara fun wa nigbati a ko ba gbe ninu ifẹ Ọlọrun iyin nigbati a ba ngbiyanju lati ṣe òfin Ọlọrun fun ra ẹni pẹlu adura laini iréti fun iru iye bẹẹ. Ifẹ Ọlọrun ni wipe ki a mọ ara wa ni ẹlẹṣẹ labẹ òfin ati wipe

    Enjoying the preview?
    Page 1 of 1