Sie sind auf Seite 1von 4

NEW ERA C&S INTERNATIONAL CHAPEL

MARY BAND ANNIVERSARY NEWS (YORUBA VERSION)

4th August, 2013

Mary Band Anniversary News (Yoruba Version)

Oro Isaju
Awa Omo egbe Mary ni oni fi ogo fun oruko Olorun, Baba Eledumare, eni ti o da ohun gbogbo, ti o si le se ohun gbogbo fun ore ofe nla ti o fi fun wa lati pejo po lati se ajodun ologo ti n se akoko iru re ni oni ojo daradara ti oluwa ti da. A fi ogo fun oruko re, ki oruko re ki o di iyin logo.

Ikini
O se pataki ki a fi ola fun eni ti ola nse tire. Nipa idi eleyi, a fi ogo fun olorun lori aye awon mama wa, Mummy G.O - Reverend Prophetess (Dr) Bose Dawodu (J.P)oludasile ijo yii ni ile yii ati loke okun, Iranse Olorun tooto, eyin - loju olodumare pelu ipe woli ti o ju ti awon woli miran lo. Woli ti olorun nba soro loju koroju , eni ti olorun ran nise ti o si n je ise naa lai se egbe . A dupe fun Ise takuntakun, ifokansin ati adura mama wa lori oke Kameli yii.(Awon Oluka iroyin naa meteta yio wa ni ikunle) A gba ni adura wipe ki oluwa ki o tubo di eyin ati ebi yi ni Nigeria ati loke okun mu sinsin (Amin). Mama wa, a ki yin wipe e ku ise oluwa, oluwa yio so agbara di otun. Ikinni wa lo si odo gbogbo awon ojise oluwa ni ori oke yii lati ori Pastor Ebenezer Olorunnisola, Assistant Pastor Femi Adewunmi, Evangelist Joseph Akinyemi, Rabbi Michael Aderibigbe ati Rabbi Taiwo Adebanji. A gba ni adura wipe ki oluwa ki o ma daabo bo yin ki o si tun so agbegbe yin di nla. (Aamin) Ope wa pataki lo si odo awon baba wa ti won je oludamoran wa eyi ti n se Assistant Pastor Femi Adewunmi fun igbiyanju won nipa ti owo,adura ati imoran lori egbe yii. A dupe gidigidi lowo yin. A si gba ni adura wipe oluwa yio gbe yin ga, yio si bukun fun yin ni gbogbo ohun ti e ba n da owo yin le (Aamin) Si iwaju si, a dupe lowo gbogbo awon alejo ti o wa ba wa se ajodun ni oni. Adura wa ni wipe oluwa yio so gbogbo yin pada si ile onikaluku yin ni ayo ati alafia ara

New Era C&S Chapel International 2013

Page | 2

Mary Band Anniversary News (Yoruba Version) (Aamin) A tun gba adura wipe bi e se pinu lati lowo si ise oluwa ni oni, oluwa yoo ma bukun si apo yin. (Aamin).

Maria Awokose wa
Gege bi a ti ka nipa re ninu iwe mimo, Maria je odomobinrin ,oniwa mimo eyi ti angeli oluwa ti a mo si Gabrieli fara han lati mu ihin rere ayo nla wa fun. Obinrin yii je eni ti a sese gbe ni iyawo fun okunrin gbena gbena kan ti a mo si Josefu. Omobinrin yii ti n se ara Juu , ni o n pinnu igbeyawo pelu oko re sugbon ti aye re yi pada si rere pelu ihin rere ayo nla ti a mu to o wa. Angeli to Maria wa ninu iwe Luku 1:28 wipe oluwa koju si lati se lore. Eleyi fi ye wa wipe, a fi ebun rere yii ta Maria lore gege bi eni ti ko ye fun sugbon ti oluwa se ni opolopo aanu ati ore ofe. Olorun woye Maria gege bi akikanju ati olugboran obinrin eyi ti o mu wa pelu omo re ti n se Jesu Kristi - titi di ojo iku Jesu oluwa wa lori igi agbelebu. Maria je eni ti o ni oye oro olorun nipa bayi , o sun fun angeli oluwa na wipe Omo Odo Oluwa, ki o ri fun mi gege bi ero okan re. O ti mo tele nipa wiwa si aye Messiah eyi ti n se olugbala araye.

Ohun ti a nilo lati se


Ti a ba wo igbesi aye Maria- eyi ti n se iya oluwa ati olugbala wa ti n se Jesu Kristi, a o ri wipe oluwa mu majemu re ti o ti ba awon eniyan da wa si imuse nipase Maria, eyi ti o fi n ye wa wipe awa naa gege bi eniyan le ma reti ohun kan lati odo oluwa, sugbon ti o ye ki a mo wipe ni igba ati akoko ti oluwa ti da, ileri naa yoo wa si imuse. Gege bi omo egbe yii, a ni lati mo wipe ko si ohun ti olorun ko le se niwon igba ti o ti le mu ileri re se nipa riran olugbala wa si aye nipase Maria. Eleyi fi ye wa wipe a ni lati fi igbekele wa sinu oluwa, ki a si di igbagbo wa mu sinsin ninu Jesu Kristi nitori wipe yoo se ohun gbogbo ti o ti se ileri fun wa.
New Era C&S Chapel International 2013 Page | 3

Mary Band Anniversary News (Yoruba Version) Si iwaju si, gege bi omo egbe rere, a ni lati se ara wa ni ebo aye mimo, itewogba niwaju oluwa, nitoriwipe eleyi je iwa amuye ti olorun ri ninu aye Maria ki o to ni oyun emi mimo. A ni lati mo daju wipe oluwa korira ese pupo pupo. Gege bi omo egbe, a gba gbogbo wa ni iyanju lati fi owo so owo po, ki a si se ise fun ifarahan ogo olorun ninu gbogbo ohun ti a ba n se. A ni lati jere okan fun Jesu laarin awon ebi wa, ijo olorun ati awujo lapaapo nipa iwa, ise ati ise isin wa. A gba ni adura wipe, bi a ti n se eleyi, anu ati ojurere olorun yoo ba aye wa. A ni igbagbo ati idaniloju wipe ti Jesu Oluwa ba fa bibo re sehin, a o tun pejo po ni iwoyi amodun lati se ajodun ologo yii ni oruko Jesu Oluwa wa (Aamin) E se pupo. Aseyi Samodun Egbe Mary-Egbe Olorire

Oro Ipari (Orin New Era)


New Era So mi dotun Ibanuje mi ti fo lo Gbogbo Omije mi ni Jesu nu Kuro New Era so mi dotun

New Era C&S Chapel International 2013

Page | 4

Das könnte Ihnen auch gefallen